14 Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongoọlá-ńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;gbé orúkọ Olúwa ga, àníỌlọ́run Ísírẹ́lì,ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;“Ògo ni fún olódodo n nì.”Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!”“Ègbé ni fún mi!Alárékérekè dalẹ̀!Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́,Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayàyóò ṣubú sínú ihò,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihòni ìdẹkùn yóò gbámú.Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rùtó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.