4 Inú ò bí mi.Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun;Èmi yóò sì dáná ṣun gbogbo wọn.
5 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi,bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lúu mi.”
6 Ní ọjọ́ iwájú Jákọ́bù yóò ta gbòǹgbò,Ísírẹ́lì yóò tanná yóò sì rudièṣo rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.
7 Ǹjẹ́ Olúwa ti lù úgẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?Ǹjẹ́ a ti pa ágẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
8 Nípa ogun-jíjà àti lílé nílùú ni ófi dojú kọ ọ́pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà oorùn fẹ́
9 Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wàfún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù,èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún tiìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ:Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹdàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrítí yóò wà ní ìdúró.
10 Ìlú olódi náà ti dahoro,ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tìgẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀;níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹkoníbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.