12 àwọn tí ó sọ fún wí pé,“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tísílẹ̀.
13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di péṣe kí o ṣe, ṣe kí o ṣe,àṣẹ lé àṣẹ, àṣẹ lé àṣẹ;díẹ̀ níhìnín, díẹ̀ ní ọ̀húnbẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubu ṣẹ́yìn,wọn yóò farapa, wọn yóò bọ́ sínú okùna ó sì gbá wọn mú.
14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,tí ń jọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jérúsálẹ́mù.
15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,kò le kàn wá lára,nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o waàti àìṣòtítọ́ ibi ipamọ́ wa.”
16 Fún ìdí náà èyí ni ohun tí Olúwa Jèhófà sọ:“Kíyèsíì, mo gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Ṣíhónìòkúta tí a dánwò,òkúta igunlé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájúẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀le kì yóò ní ìfòyà.
17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀nàti òdòdó òjé òṣùwọ̀n;yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tíẹ ń farapamọ́ sí mọ́lẹ̀.
18 Májẹ̀muu yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fagi lé;àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.