1 Ègbé ni fún ọ, Áríẹ́lì, Áríẹ́lì,ìlú níbi tí Dáfídì tẹ̀dó sí!Fi ọdún kún ọdúnsì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀ṣíwájú.
2 Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ èmi yóò dó ti Áríẹ́lìòun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sunkún,òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
3 Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;Èmi yóò sì fi ilé-ìṣọ́ yí ọ ká:èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdótini mi dojú kọ ọ́.
4 Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti iwin láti ilẹ̀ wá,láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹyóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
5 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.Lójijì, ní ìṣẹ́jú àáyá,