Àìsáyà 29:4-10 BMY

4 Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti iwin láti ilẹ̀ wá,láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹyóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

5 Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.Lójijì, ní ìṣẹ́jú àáyá,

6 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wápẹ̀lú àrá, ilẹ̀ ríri àti ariwo ńláàti ẹ̀fúúfù líle àti iná ajónirunorílẹ̀ èdè tí ó bá Áríẹ́lì jà,tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódì rẹ̀tí ó sì dó tì í,yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,bí ìran ní òru

7 Lẹ́yìn náà,ọ̀gọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo

8 àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá péòun ń jẹun,ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀;àti bí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá péòun ń mumi,ṣùgbọ́n nígbà tí ó yajú pẹ́ ẹ́, pẹ̀lú òùngbẹtí kò dáwọ́ dúró ni.Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdètí ń bá òkè Ṣíhónì jà.

9 Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,ẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n kì í se ti ọtí bíà.

10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sóríi yín:ó ti dì yín lójú (ẹ̀yin wòlíì);ó ti bo oríi yín (ẹ̀yin aríran).