1 Kíyèsí i, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jérúsálẹ́mù àti Júdàgbogbo ìpèsè ounjẹ àti ìpèsè omi
2 àwọn akíkanjú àti jagunjagun,adájọ́ àti wòlíì,aláfọ̀sẹ àti alàgbà,
3 balógun àádọ́ta àti bọ̀rọ̀kìnní ènìyàn,olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́àti ògbójú oníṣegùn.
4 Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sìmáa jọba lóríi wọn.
5 Àwọn ènìyàn yóò sì má a pọ́nọmọnìkejì wọn lójúẹnìkan sí ẹnìkejìi rẹ̀, aládùúgbòsí aládùúgbò rẹ̀.Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbogun ti àwọn àgbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí bọ̀rọ̀kìnní.
6 Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínu àwọnarákùnrin rẹ̀ múnínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,“Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
7 Ṣùgbọn ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,“Èmi kò ní àtúnṣe kan.Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ò ní aṣọ nílé,ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”