1 “Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè alágídí náà,”ni Olúwa wí,“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;
2 tí wọ́n lọ sí Éjíbítìláì ṣe fún mi,tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Fáráò fún ààbò,sí òjìji, Éjíbítì fún ibi ìsádi.
3 Ṣùgbọ́n ààbò Fáráò yóò já sí ìtìjú fún un yín,òjìji Éjíbítì yóò mú àbùkù báa yín.
4 Bí wọ́n tilẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ ní Sóánìtí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hánísì,