10 Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”àti fún àwọn wòlíì,“Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
11 Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,ẹ kúrò ní ọ̀nà yìíẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọwápẹ̀lú Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì!”
12 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì wí:“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,ẹ gbáralé ìnilárakí ẹ sì gbọ́kànlé ẹ̀tàn,
13 ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọgẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fìtí ó sì wó lójijì, àti ńi ìṣẹ́jú àáyá.
14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdìtí a fọ́ yánkanyànkanàti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,fún mímú èédú kúrò nínú ààròtàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”
15 Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára, Ẹni-Mímọ́ ti Ísírẹ́lì wí:“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16 Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’Nítorí náà àwọn tí ń lée yín yóò yára!