14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdìtí a fọ́ yánkanyànkanàti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,fún mímú èédú kúrò nínú ààròtàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”
15 Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára, Ẹni-Mímọ́ ti Ísírẹ́lì wí:“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16 Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’Nítorí náà àwọn tí ń lée yín yóò yára!
17 Ẹgbẹ̀rún yóò sánípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn úngbogbo yín lẹ ó ṣálọ,tí a ó fi yín sílẹ̀àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè,gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè.”
18 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;ó dìde láti ṣàánú fún ọ.Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!
19 Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò farasin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.