Àìsáyà 30:24-30 BMY

24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi amúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀.

25 Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀míi wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò ṣàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré.

26 Òṣùpá yóò sì tàn bí òòrùn, àti ìtànsán òòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27 Kíyèsí i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wápẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kùrukùruèéfín tí ó nípọn;ètè rẹ̀ kún fún ìbínúahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.

28 Èémíi rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,tí ó rú sókè dé ọ̀run.Ó jọ àwọn orílẹ̀ èdè nínú asẹ́ ìparun;ó sì fi sí àgbọ̀n àwọn ènìyànkókó kan tí ó ń sì wọ́n lọ́nà.

29 Ẹ̀yin ó sì kọringẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,ọkàn yín yóò yọ̀gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lúu fèrèsí orí òkè Olúwa,àní sí àpáta Ísírẹ́lì.

30 Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,pẹ̀lúu mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.