Àìsáyà 36:3-9 BMY

3 Eliákímù ọmọ Hílíkáyà alábojútó ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.

4 Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Heṣekáyà,“ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Áṣíríà sọ pé: Lóríi kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?

5 Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ aṣán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?

6 Wò ó nísinsìn yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì ẹ̀rúnrún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sìí dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e.

7 Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni Heṣekáyà ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájúu pẹpẹ yìí”?

8 “ ‘Ẹ wá nísinsìn yìí, bá ọ̀gá mi pàmọ̀ pọ̀, ọba Ásíríà: Èmi yóò fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!

9 Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kanṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn ìjòyè ọ̀gá mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé Éjíbítì fún kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin?