Àìsáyà 37:1-7 BMY

1 Nígbà tí ọba Heṣekáyà gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara rẹ̀, ó sì wọ inú tẹ́ḿpìlì Olúwa lọ.

2 Òun sì rán Eliákímù alákoṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì.

3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Heṣekáyà sọ: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọdé kùdẹ̀dẹ̀ ìbí tí kò sì sí agbára láti bí wọn.

4 Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Ásíríà ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láàyè.”

5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Heṣekáyà dé ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,

6 Àìṣáyà sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi.

7 Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”