12 Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì?
13 Níbo ni ọba Hámátì wà, ọba Ápádì, ọba Ìlú Ṣefáfíámù tàbí Hénà tàbí Ífà?”
14 Heṣekáyà gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa.
15 Heṣekáyà sì gbàdúrà sí Olúwa:
16 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó gúnwà láàrin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lóríi gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
17 Tẹ́tí sílẹ̀, Ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ṣenakérúbù rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
18 “Òtítọ́ ni ìwọ Olúwa pé àwọn ọba Ásíríà ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.