17 Tẹ́tí sílẹ̀, Ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ṣenakérúbù rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
18 “Òtítọ́ ni ìwọ Olúwa pé àwọn ọba Ásíríà ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.
19 Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.
20 Nísinsìn yìí, Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ọ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”
21 Lẹ́yìn náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán iṣẹ́ kan sí Heṣekáyà: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ pé: Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà,
22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíhónìkẹ́gàn ó sì fi ọ ṣe yẹ̀yẹ́.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi oríi rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.
23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀ òdì sí?Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókètí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì!