Àìsáyà 37:20-26 BMY

20 Nísinsìn yìí, Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ọ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”

21 Lẹ́yìn náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán iṣẹ́ kan sí Heṣekáyà: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ pé: Nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Ṣenakérúbù ọba Áṣíríà,

22 èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíhónìkẹ́gàn ó sì fi ọ ṣe yẹ̀yẹ́.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi oríi rẹ̀ bí ó ti ń sálọ.

23 Ta ni ìwọ ti bú tí ìwọ sì ti sọ̀rọ̀ òdì sí?Sí ta ní ìwọ ti gbé ohùn rẹ sókètí o sì gbé ojú rẹ sókè ní ìgbéraga?Sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì!

24 Nípa àwọn oníṣẹ́ rẹìwọ ti mú àbùkù bá Olúwa.Ìwọ sì ti sọ wí pé‘pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin miÈmi ti gun orí òkè ńlá ńlá,ibi gíga jùlọ ti Lébánónì.Èmi ti gé igi kédárì rẹ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,àti àyànfẹ́ igi páínì.Èmi ti dé ibi rẹ̀ tí ó ga jùlọ,igbó rẹ̀ tí ó dára jùlọ.

25 Èmi ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìmo sì mu omi ní ibẹ̀,pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ miÈmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Éjíbítì.’

26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́?Tipẹ́ tipẹ́ ni mo ti fìdíi rẹ̀ mulẹ̀.Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,pé o ti sọ àwọn ìlú olódi diàkójọpọ̀ àwọn òkúta