25 Èmi ti gbẹ́ kàǹga ní ilẹ̀ àjèjìmo sì mu omi ní ibẹ̀,pẹ̀lú àtẹ́lẹṣẹ̀ miÈmi ti gbẹ́ gbogbo omi àwọn odò Éjíbítì.’
26 “Ṣé o kò tí ì gbọ́?Tipẹ́ tipẹ́ ni mo ti fìdíi rẹ̀ mulẹ̀.Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,pé o ti sọ àwọn ìlú olódi diàkójọpọ̀ àwọn òkúta
27 Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhù tuntun,gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,tí ó jóná kí ó tó dàgbà ṣókè.
28 “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wààti ìgbà tí o wá tí o sì lọàti bí inú rẹ ṣe ru sími.
29 Nítorí pé inú rẹ ru símiàti nítorí pé oríkunkun rẹ tidé etíìgbọ́ mi,Èmi yóò fi ìwọ mi sí ọ ní imú,àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,èmi yóò sì jẹ́ kí o padàláti ọ̀nà tí o gbà wá.
30 “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà:“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn.
31 Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́ku láti ilé Júdàyóò ta gbòǹgbò níṣàlẹ̀ yóò sì ṣo èṣo lókè.