3 Wọ́n sọ fún un pé, “Báyìí ni Heṣekáyà sọ: ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́, ìbáwí àti ìtìjú gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọdé kùdẹ̀dẹ̀ ìbí tí kò sì sí agbára láti bí wọn.
4 Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Ásíríà ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láàyè.”
5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Heṣekáyà dé ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,
6 Àìṣáyà sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi.
7 Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Áṣíríà ti fi Lákísì sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Líbínà jà.
9 Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: