5 Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Heṣekáyà dé ọ̀dọ̀ Àìṣáyà,
6 Àìṣáyà sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí: Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Ásíríà tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀ òdì sí mi.
7 Tẹ́tísílẹ̀! Èmi yóò fi ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí o bá ti gbọ́ ìròyìn kan, òun yóò padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀, níbẹ̀ ni n ó sì ti jẹ́ kí wọn ké e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
8 Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Áṣíríà ti fi Lákísì sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Líbínà jà.
9 Ní àkókò yìí Ṣenakérúbù gbọ́ ìròyìn kan pé Tíhákà ará Kúṣì ọba Éjíbítì ń jáde bọ̀ wá bá òun jà. Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó rán oníṣẹ́ sí Heṣekáyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
10 “Ẹ sọ fún Heṣekáyà ọba Júdà pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘a kì yóò jọ̀wọ́ Jérúsálẹ́mù fún ọba Ásíríà.’
11 Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Ásíríà ti ṣe sí àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó pa wọ́n run pátapáta. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?