16 Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé;àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú un wọn pẹ̀lú.Ìwọ dá ìlera mi padàkí o sì jẹ́ kí n wà láàyè
17 Nítòótọ́ fún àǹfààní mi nipé mo jẹ ìyà irú ìpọ́njú báyìí.Nínú ìfẹ́ rẹ ni o pamí mọ́kúrò nínú ọ̀gbun ìparun;ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
18 Nítorí pé iṣà òkú kò le è yìn ọ́,ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ;àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbunkò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
19 Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́,gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí;àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
20 Olúwa yóò gbà mí làbẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókunní gbogbo ọjọ́ ayé wanínú tẹ́ḿpìlì ti Olúwa.
21 Àìṣáyà ti sọ pé, “Pèṣè ìsù (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”
22 Heṣekáyà ti sọ pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa?”