17 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.
18 “Gbọ́, ìwọ adití,wòó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!
19 Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?
20 Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkankan.”
21 Ó dùn mọ́ Olúwanítorí òdodo rẹ̀láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.
22 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan níyìí tí a jà lóguntí a sì kó lẹ́rú,gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.Wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
23 Ta ni nínú un yín tí yóò tẹ́tí sí èyítàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?