1 Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bùẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì:“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;Èmi ti pè ọ́ ní orúkọtèmi ni ìwọ ṣe.
2 Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ,Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.
4 Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.