17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:
18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá,láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22 “Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,Ìwọ Jákọ́bù,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì miÌwọ Ísírẹ́lì.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan,tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhórótàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.