18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá,láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21 àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.
22 “Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,Ìwọ Jákọ́bù,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì miÌwọ Ísírẹ́lì.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ ọrẹ sísan,tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ oníhórótàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kálámọ́ọ́sì olóòórùndídùn fún mi,tàbí kí o da ọ̀rá-ẹbọ rẹ bò mí.Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yínẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedédé yín.