8 Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
9 Gbogbo orílẹ̀ èdè kóra wọn jọàwọn ènìyàn sì kóra wọn papọ̀.Ta ni nínú wọn tó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ yìítí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wáláti fi hàn pé wọ́n tọ̀nàtó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tíwọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà ḿi gbọ́tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,tàbí a ó wa rí òmìíràn lẹ́yìn mi.
11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kédeÈmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín.Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13 Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”
14 Èyí ni ohun tí Olúwa wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.