1 “Ṣùgbọ́n tẹ́tísílẹ̀ nísinsìn yìí, Ìwọ Jákọ́bù,Ìránṣẹ́ miÍsírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn.
2 Ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́láti inú ìyá rẹ wá,àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi,Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.
3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ;Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
4 Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínúpápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.