Àìsáyà 44:2-8 BMY

2 Ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́láti inú ìyá rẹ wá,àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi,Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.

3 Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ;Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.

4 Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínúpápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.

5 Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù;bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa,yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.

6 “Ohun tí Olúwa wí nìyìíọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun:Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan.

7 Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú miKí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdíàwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.

8 Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́?Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kanha ń bẹ lẹ́yìn mi?Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”