6 Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọnwọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n;wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,wọn sì tẹríba láti sìn ín.
7 Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,wọ́n sì gbé e sí àye rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.Láti ibẹ̀ náà kò le è paradàBí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́tijọ́;Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlọ̀mìíràn;Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmìíràn bí ì mi.
10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.Mo wí pé: Ète mi yóò dúró,àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò múṣẹ;èyí tí mo ti gbérò, òun ni èmi yóò ṣe.
12 Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọlọ́kàn-dídi,ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.