12 “Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹàti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà nió ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀láti oṣù dé oṣù,jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.
14 Lóòótọ́ wọ́n dàbí pòpó;iná ni yóò jó wọn dànù.Wọn kò kúkú lè gba ara wọn làlọ́wọ́ agbára iná náà.Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbónáníhìnín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
15 Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìígbogbo èyí ní o tí síṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.