7 Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé—ọba-bìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
8 “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’
9 Méjèèjì yìí ni yóò wá sóríì rẹláìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà:pípàdánù ọmọ àti dídi opó.Wọn yóò wá sóríì rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹàti àwọn èpè rẹ tí kì í ṣélẹ̀.
10 Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’Ọgbọ́n àti òye rẹ ti sì ọ́ lọ́nànígbà tí o wí fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.’
11 Ìparun yóò dé bá ọbẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;òfò kan tí o kò le ròtì niyóò wá lójijì sí oríì rẹ.
12 “Tẹ̀ṣíwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹàti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà nió ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀láti oṣù dé oṣù,jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.