9 Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò.
10 Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
11 Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyíBáwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn.
12 “Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bùÍsírẹ́lì ẹni tí mo pè:Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.
14 “Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí:Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹló ti sọ nǹkan wọ̀nyí?Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwani yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì;apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.
15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.