12 Kíyèsí i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jínjìnàwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀láti ìwọ̀ oòrùn,àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Áṣíwánì.”
13 Ẹ hó fún ayọ̀, Ẹ̀yin ọ̀run;yọ̀, ìwọ ilẹ̀-ayé;bú sórin, ẹ̀yin òkè-ńlá!Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínúyóò sì ṣàánú fún àwọn ẹnití a ń pọ́n lójú.
14 Ṣùgbọ́n Ṣíhónì sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.”
15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbéÈmi kì yóò gbàgbé rẹ!
16 Kíyèsí i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ miògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
18 Gbójú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká;gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọwọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè,” ni Olúwa wí,“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.