1 Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì,wọ ara rẹ ní agbára.Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì.Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́kì yóò wọ inú un rẹ mọ́.
2 Gbọn eruku rẹ kúrò;dìde ṣókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jérúsálẹ́mù.Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbékùn Ṣíhónì.
3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀lọ sí Éjíbítì láti gbé;láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú.