1 Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì,wọ ara rẹ ní agbára.Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì.Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́kì yóò wọ inú un rẹ mọ́.
2 Gbọn eruku rẹ kúrò;dìde ṣókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jérúsálẹ́mù.Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,Ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbékùn Ṣíhónì.
3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀lọ sí Éjíbítì láti gbé;láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú.
5 “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”ni Olúwa wí.“Àti ní ọjọọjọ́orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo.
6 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”
7 Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkèẹṣẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìn rere ayọ̀ wá,tí wọ́n kéde àlàáfíà,tí ó mú ìyìn rere wá,tí ó kéde ìgbàlà,tí ó sọ fún Ṣíhónì pé,“Ọlọ́run rẹ ń jọba!”