Àìsáyà 57:7-13 BMY

7 Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8 Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yínníbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí.Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀,ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada;ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn,ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.

9 Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífìẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín,ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’Ẹ rí okun kún agbára yín,nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.

11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rùtí ẹ fi ń ṣèké sí mi,àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mitàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

12 Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín,wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ni yóò jogún ilẹ̀ náàyóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”