Àìsáyà 58:1-6 BMY

1 “Kígbe rẹ̀ ṣókè, má ṣe fà ṣẹ́yìn.Gbé ohùn rẹ ṣókè bí i ti fèrè.Jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún áwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọnàti fún ilé Jákọ́bù ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

2 Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nàtí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkanwọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.

3 ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’“Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ní ọjọ́ ààwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yínẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.

4 Ààwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,àti lílu ọmọnìkejì ẹni pẹ̀lú ẹṣẹ́ ìkà.Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìíkí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.

5 Ǹjẹ́ èyí ha ni irú ààwẹ̀ tí mo yàn bí,ọjọ́ kanṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?Í haá ṣe kí ènìyàn tẹ orí i rẹ̀ ba bí i koríko láṣán ni bíàti ṣíṣùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ nìyí,ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

6 “Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodoàti láti tú gbogbo okùn àjàgà,láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?