Àìsáyà 6:5-11 BMY

5 “Ègbé ni fún mi!” Ni mo ké, “Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

6 Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ.

7 Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wòó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

8 Lẹ́yìn náà, mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni n ó rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”Èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

9 Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn mi lọ kí o sì wí pé;“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;ní rírí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,mú kí wọn kútíkí o sì pa ojú wọn dé.Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ojú u wọn ríran,ki wọn má ba à fi etíi wọn gbọ́ràn,kí òye máa ba à yé wọn ní ọkàn an wọnkí wọn má ba à yípadà kí a má ba à sì wò wọ́n sàn.”

11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”Òun sì dáhùn pé:“Títí tí gbogbo ìlú ńlá yóò fi dahoroláìsí olùgbé nínú un rẹ̀ mọ́,títí tí gbogbo ilé yóò fi di ìkọ̀sílẹ̀tí gbogbo ilé yóò sì di àlàpà àti ahoro,