Àìsáyà 60:3-9 BMY

3 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

4 “Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ:Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn,àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá.

5 Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,ọkàn rẹ yó fó yó sì kún fún ayọ̀;ọrọ̀ inú òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá.

6 Ọ̀wọ́ ràkunmí yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,àwọn ọ̀dọ́ ràkunmí Mídíánì àti Ẹfà.Àti gbogbo wọn létí Ṣèbà yóò wá,wọn yóò mú Góòlù àti tùràrí lọ́wọ́tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

7 Gbogbo agbo ẹran Kédárì ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,àwọn àgbò ti Nébáíótì yóò sìn ọ́;wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi,bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹ́ḿpìlì ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

8 “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kùrukùru,gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

9 Lótìítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Táṣíṣì;mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn,pẹ̀lú fàdákà àti góòlùu wọn,fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.