Àìsáyà 66:4-10 BMY

4 Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọnn ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tísílẹ̀.Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú miwọ́n sì yan ohun tí mo kóríìra rẹ̀.”

5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kóríra yín,tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,kí a le rí ayọ̀ yín!’Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

6 Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá,gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá!Ariwo tí Olúwa ní í ṣetí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohuntí ó tọ́ sí wọn.

7 “Kí ó tó lọ sí ìrọbí,ó ti bímọ;kí ó tó di pé ìrora dé bá a,ó ti bí ọmọkùnrin.

8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kantàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbíbẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bíkí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọnígbà tí mo ń mú ìbí wá?” ni Ọlọ́run yín wí.

10 “Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.