Àìsáyà 66:6-12 BMY

6 Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá,gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá!Ariwo tí Olúwa ní í ṣetí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohuntí ó tọ́ sí wọn.

7 “Kí ó tó lọ sí ìrọbí,ó ti bímọ;kí ó tó di pé ìrora dé bá a,ó ti bí ọmọkùnrin.

8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kantàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbíbẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bíkí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọnígbà tí mo ń mú ìbí wá?” ni Ọlọ́run yín wí.

10 “Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.

11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùnnínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára;Ẹ̀yin yóò mu àmuyóẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

12 Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.