9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bíkí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọnígbà tí mo ń mú ìbí wá?” ni Ọlọ́run yín wí.
10 “Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùnnínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára;Ẹ̀yin yóò mu àmuyóẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12 Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”
14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15 Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.