2 Báyìí, a sọ fún ilé Dáfídì pé, “Árámù mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfáímù”; fún ìdí èyí, ọkàn Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
3 Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Àìṣáyà pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣéárì-Jáṣúbù láti pàdé Áhásì ní ìpẹ̀kun ìṣàn-omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
4 Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.
5 Árámù, Éfáímù àti Rèmálíà ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,
6 “Jẹ́ kí a kọlu Júdà; jẹ́ kí a fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kí a sì pín in láàrin ara wa, kí a sì fi ọmọ Tábẹ́lì jọba lóríi rẹ̀.”
7 Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“ ‘Èyí kò ní wáyéÈyí kò le ṣẹlẹ̀,
8 nítorí Dámásíkù ni orí Árámù,orí Dámásíkù sì ni Résínì.Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́taÉfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.