5 Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì pa majẹmu mi mọ́ ẹ óo jẹ́ tèmi láàrin gbogbo eniyan, nítorí pé tèmi ni gbogbo ayé yìí patapata;
6 ẹ óo di ìran alufaa ati orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
7 Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn.
8 Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
9 OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.”Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
10 OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta,
11 nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn.