1 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo
2 láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọnàti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúròníwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní lólè.
3 Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirònígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jínjìn wá?Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
4 Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.