3 Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirònígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jínjìn wá?Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
4 Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrin àwọn ìgbèkùntàbí kí o ṣubú sáàrin àwọn tí a pa.Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.
5 “Ègbé ni fún àwọn ará Ásíríà, ọ̀gọ ìbínú mi,ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
6 Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́runMo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínúláti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógunláti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
7 Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;èrò rẹ̀ ni láti parun,láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.
8 ‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
9 ‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì?Hámátì kò ha dàbí i Ápádì,àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?