6 Mo rán an sí orílẹ̀ èdè aláìní Ọlọ́runMo dojúu rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó múmi bínúláti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógunláti tẹ̀mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
7 Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;èrò rẹ̀ ni láti parun,láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè.
8 ‘Kì í haá ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
9 ‘Kì í ha á ṣe pé Kálínò dàbí i Káṣẹ́míṣì?Hámátì kò ha dàbí i Ápádì,àti Ṣamáríà bí i Dámásíkù?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,Ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jérúsálẹ́mù àti Ṣamáríà lọ.
11 Èmi kì yóò a bá Jérúsálẹ́mù wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Ṣamáría àti àwọn ère rẹ̀?
12 Nígbà tí Olúwa bá parí iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Ṣíhónì àti Jérúsálẹ́mù, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ Ásíríà nítoríi gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojúu rẹ̀.