18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀ èdè ni a tẹ́ sílẹ̀ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojìgẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀ sílẹ̀,àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,àwọn tí idà ti gún,àwọn tí ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀,
20 A kò ní sin ọ́ pẹ̀lúu wọn,nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.Ìran àwọn ìkàni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
21 Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹnítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńláa wọn,wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlúu wọn.
22 “Èmi yóò dìde ṣókè sí wọn,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti àwọn tí ó sálà,àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”ni Olúwa wí.
23 “Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwíàti sí irà;Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,”ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.