25 Èmi yóò run Ásíríà ní ilẹ̀ mi,ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìkáa wọn.”
26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè.
27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
28 Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Áhásì kú:
29 Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì,pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;láti ibi gbòngbò ejò náà ni pamọ́lẹ̀yóò ti hù jáde,èṣo rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tíí jóni.
30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.Ṣùgbọ́n gbòǹgbòo rẹ ni èmi ó fi ìyàn parun,yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.
31 Kígbe, Ìwọ ẹnu ọ̀nà! Pariwo, Ìwọ ìlú!Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Fílístínì!Kurukuru èéfín kan ti Àríwá wá,kò sì sí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.