5 Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
6 èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdèpẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
7 Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,wọ́n bú sí orin.
8 Pẹ̀lú pẹ̀lù àwọn igi Páínì àti àwọnigi kédárì ti Lẹ́bánónìń yọ̀ lóríì rẹ ó wí pé,“Níwọ̀n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,kò sí alagi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”
9 Ibojì tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni a ru sókèláti pàdé rẹ ní àpadàbọ̀ rẹ̀ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ ṣókè láti wá kí ọgbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayéó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ẹ wọngbogbo àwọn tí ó jọba lórí àwọn orílẹ̀ èdè.
10 Gbogbo wọn yóò dáhùn,wọn yóò wí fún ọ wí pé,“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lúìwọ náà ti dàbí wa.”
11 Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,pẹ̀lú ariwo àwọn hápù rẹ,àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹàwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.