2 Díbónì gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlìi rẹ̀,sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti ṣunkún,Móábù pohùnréré lórí Nébónì àti Médíbà.Gbogbo orí ni a fágbogbo irungbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede àkójọwọ́n pohùnréré,Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Hẹ́ṣíbónì àti Élíálè ké ṣóde,ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jáhásì.Nítorí náà ni àwọn ọmọ ogun Móábù ṣe kígbetí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ́sì.
5 Ọkàn mi kígbe lórí Móábù;àwọn ìṣáǹṣá rẹ sálà títí dé Ṣóárì,títí fi dé Égílátì Ṣẹ́líṣíyà.Wọ́n gòkè lọ títí dé Lúhítìwọ́n ń ṣunkún bí wọ́n ti ń lọ,Ní òpópónà tí ó lọ sí Hórónáímùwọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6 Gbogbo omi Nímírímù ni ó ti gbẹàwọn koríko sì ti gbẹ,gbogbo ewéko ti tánewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti nítí wọ́n sì tòjọwọ́n ti kó wọn kọjá lọ lóríi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́odò pópúlárì.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn déìpẹ̀kun ilẹ̀ Móábù;ìpohùnréré wọn lọ títí dé Ẹgíláémù,igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Élímù.