22 Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilée Dáfídì lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá sí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ẹnikẹ́ni kì yóò le è sí.
23 Èmi yóò sì kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní àyèe rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.
24 Gbogbo ògo ìdílée rẹ̀ ni yóò rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ gbogbo ohun èlò aláìlágbára láti orí abọ́ rẹ̀ dé orí ìdẹ̀ rẹ̀.
25 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní àyèe rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lóríi rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.